Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 18:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere.

12. Nwọn si wipe: Lasan ni: nitori awa o rìn nipa ipinnu wa, olukuluku yio si huwa agidi ọkàn buburu rẹ̀.

13. Nitorina bayi li Oluwa wí, Ẹ sa bère ninu awọn orilẹ-ède, tani gbọ́ iru ohun wọnni: wundia Israeli ti ṣe ohun kan ti o buru jayi.

14. Omi ojo-didì Lebanoni yio ha dá lati ma ṣàn lati apata oko? tabi odò ti o jina, ti o tutu, ti o nṣan, yio ha gbẹ bi?

15. Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́.

16. Lati sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹ̀gan lailai; olukuluku ẹniti o ba kọja nibẹ, yio dãmu yio mì ori rẹ̀ si i.

17. Emi o tú wọn ka gẹgẹ bi ẹ̀fufu ila-õrùn niwaju ọta wọn; emi o kọ ẹ̀hin mi si wọn, kì yio ṣe oju mi, ni ọjọ iparun wọn.

18. Nigbana ni nwọn wipe, Wá, ẹ jẹ ki a pinnu ìwa ibi si Jeremiah, nitori ofin kì yio ṣegbe lọwọ alufa, tabi igbimọ lọwọ ọlọgbọ́n, tabi ọ̀rọ lọwọ woli: ẹ wá, ẹ jẹ ki a fi ahọn wa lù u, ki a má si kiyesi ohun kan ninu ọ̀rọ rẹ̀.

19. Kiyesi mi, Oluwa, ki o si gbọ́ ohùn awọn ti nni mi lara.

20. A ha le fi ibi san rere? nitori nwọn ti wà iho fun ẹmi mi. Ranti pe emi ti duro niwaju rẹ lati sọ ohun rere nipa ti wọn, ati lati yi ibinu rẹ kuro lọdọ wọn.

21. Nitorina, fi awọn ọmọ wọn fun ìyan, ki o si fi idà pa wọn, jẹ ki aya wọn ki o di alailọmọ ati opó: ki a si fi ìka pa awọn ọkunrin wọn, jẹ ki a fi idà pa awọn ọdọmọde wọn li ogun.

22. Jẹ ki a gbọ́ igbe lati ilẹ wọn, nigbati iwọ o mu ẹgbẹ kan wá lojiji sori wọn: nitori nwọn ti wà ihò lati mu mi, nwọn si dẹ okùn fun ẹsẹ mi.

23. Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ mọ̀ gbogbo igbimọ wọn si mi lati pa mi, máṣe bò ẹbi wọn mọlẹ, bẹ̃ni ki iwọ máṣe pa ẹṣẹ wọn rẹ́ kuro niwaju rẹ, jẹ ki nwọn ki o ṣubu niwaju rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe si wọn ni ọjọ ibinu rẹ.

Ka pipe ipin Jer 18