Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 18:11-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere.

12. Nwọn si wipe: Lasan ni: nitori awa o rìn nipa ipinnu wa, olukuluku yio si huwa agidi ọkàn buburu rẹ̀.

13. Nitorina bayi li Oluwa wí, Ẹ sa bère ninu awọn orilẹ-ède, tani gbọ́ iru ohun wọnni: wundia Israeli ti ṣe ohun kan ti o buru jayi.

14. Omi ojo-didì Lebanoni yio ha dá lati ma ṣàn lati apata oko? tabi odò ti o jina, ti o tutu, ti o nṣan, yio ha gbẹ bi?

15. Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́.

16. Lati sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹ̀gan lailai; olukuluku ẹniti o ba kọja nibẹ, yio dãmu yio mì ori rẹ̀ si i.

17. Emi o tú wọn ka gẹgẹ bi ẹ̀fufu ila-õrùn niwaju ọta wọn; emi o kọ ẹ̀hin mi si wọn, kì yio ṣe oju mi, ni ọjọ iparun wọn.

18. Nigbana ni nwọn wipe, Wá, ẹ jẹ ki a pinnu ìwa ibi si Jeremiah, nitori ofin kì yio ṣegbe lọwọ alufa, tabi igbimọ lọwọ ọlọgbọ́n, tabi ọ̀rọ lọwọ woli: ẹ wá, ẹ jẹ ki a fi ahọn wa lù u, ki a má si kiyesi ohun kan ninu ọ̀rọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Jer 18