Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 18:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ̀ Oluwa wipe,

2. Dide, sọkalẹ lọ si ile amọkoko, nibẹ li emi o mu ọ gbọ́ ọ̀rọ mi.

3. Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ.

4. Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ.

5. Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

6. Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.

7. Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run.

8. Bi orilẹ-ède na ti mo ti sọ ọ̀rọ si ba yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀, emi o yi ọkàn mi pada niti ibi ti emi ti rò lati ṣe si wọn.

9. Ati lojukanna ti emi sọ ọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan, lati tẹ̀ ẹ do ati lati gbìn i.

10. Bi o ba ṣe ibi niwaju mi, ti kò si gbà ohùn mi gbọ́: nigbana ni emi o yi ọkàn mi pada niti rere, eyiti mo wi pe, emi o ṣe fun wọn.

11. Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere.

12. Nwọn si wipe: Lasan ni: nitori awa o rìn nipa ipinnu wa, olukuluku yio si huwa agidi ọkàn buburu rẹ̀.

13. Nitorina bayi li Oluwa wí, Ẹ sa bère ninu awọn orilẹ-ède, tani gbọ́ iru ohun wọnni: wundia Israeli ti ṣe ohun kan ti o buru jayi.

14. Omi ojo-didì Lebanoni yio ha dá lati ma ṣàn lati apata oko? tabi odò ti o jina, ti o tutu, ti o nṣan, yio ha gbẹ bi?

15. Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́.

16. Lati sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹ̀gan lailai; olukuluku ẹniti o ba kọja nibẹ, yio dãmu yio mì ori rẹ̀ si i.

Ka pipe ipin Jer 18