Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 16:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nitorina, sa wò o, Bayi li Oluwa wi, ọjọ mbọ̀, ti a kì o wi mọ́ pe, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti;

15. Ṣugbọn, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.

16. Sa wò o, emi o ran apẹja pupọ, li Oluwa wi, nwọn o si dẹ wọn: lẹhin eyini, emi o rán ọdẹ pupọ, nwọn o si dẹ wọn lati ori oke-nla gbogbo, ati ori oke kekere gbogbo, ati lati inu palapala okuta jade.

17. Nitoriti oju mi mbẹ lara ọ̀na wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹ̃ni ẹ̀ṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi.

18. Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.

19. Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn!

20. Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun?

Ka pipe ipin Jer 16