Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 15:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si wi fun mi pe, Bi Mose ati Samueli duro niwaju mi, sibẹ inu mi kì yio si yipada si awọn enia yi: ṣá wọn tì kuro niwaju mi, ki nwọn o si jade lọ.

2. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, nibo ni awa o jade lọ? ki iwọ ki o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; awọn ti ikú, si ikú, awọn ti idà, si idà; ati awọn ti ìyan, si ìyan, ati awọn ti igbèkun si igbèkun.

3. Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun.

4. Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu.

5. Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.

6. Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.

Ka pipe ipin Jer 15