Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 13:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Bẹ̃ni mo lọ, emi si fi i pamọ leti odò Ferate, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun mi.

6. O si ṣe lẹhin ọjọ pupọ, Oluwa wi fun mi pe, Dide, lọ si odò Ferate, ki o si mu amure nì jade, ti mo paṣẹ fun ọ lati fi pamọ nibẹ.

7. Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun.

8. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

9. Bayi li Oluwa wi, Gẹgẹ bi eyi na ni emi o bà igberaga Juda jẹ, ati igberaga nla Jerusalemu.

10. Awọn enia buburu yi, ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi, ti nrin ni agidi ọkàn wọn, ti o si nrin tọ̀ awọn ọlọrun miran, lati sìn wọn ati lati foribalẹ fun wọn, yio si dabi àmure yi, ti kò yẹ fun ohunkohun.

11. Nitori bi amure iti lẹ̀ mọ ẹgbẹ enia, bẹ̃ni mo ṣe ki gbogbo ile Israeli ati gbogbo ile Juda ki o lẹ̀ mọ mi lara, li Oluwa wi, ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ati orukọ ati ogo, ati iyìn, ṣugbọn nwọn kò fẹ igbọ́.

12. Nitorina ki iwọ ki o sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún: nwọn o si wi fun ọ pe, A kò ha mọ̀ nitõtọ pe, gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún?

13. Nigbana ni iwọ o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi imutipara kún gbogbo olugbe ilẹ yi, ani awọn ọba ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn alufa ati awọn woli, pẹlu gbogbo awọn olugbe Jerusalemu.

14. Emi o tì ekini lu ekeji, ani awọn baba ati awọn ọmọkunrin pọ̀, li Oluwa wi: emi kì yio dariji, bẹ̃ni emi kì o ṣãnu, emi kì yio ṣe iyọ́nu, lati má pa wọn run.

Ka pipe ipin Jer 13