Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 13:20-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Gbe oju nyin soke, ki ẹ si wo awọn ti mbọ̀ lati ariwa! nibo ni agbo-ẹran nì wà, ti a ti fi fun ọ, agbo-ẹran rẹ daradara?

21. Kini iwọ o wi, nigbati on o fi awọn ti iwọ ti kọ́ lati ṣe korikosun rẹ jẹ olori lori rẹ, irora kì yio ha mu ọ bi obinrin ti nrọbi?

22. Bi iwọ ba si wi ninu ọkàn rẹ pe, Ẽṣe ti nkan wọnyi ṣe wá sori mi? Nitori ti ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ ni a ṣe ká aṣọ rẹ soke, ti a si fi agbara fi gigisẹ rẹ hàn ni ihoho.

23. Ara Etiopia le yi àwọ rẹ̀ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ̀ pada? bẹ̃ni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ́ ni ìwa buburu?

24. Nitorina ni emi o tú wọn ka bi iyangbo ti nkọja lọ niwaju afẹfẹ aginju.

25. Eyi ni ipin rẹ, apakan òṣuwọn rẹ lọwọ mi, li Oluwa wi: nitori iwọ ti gbàgbe mi, ti o si gbẹkẹle eke.

Ka pipe ipin Jer 13