Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 13:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi fun mi pe: Lọ, ki o si rà àmure aṣọ ọgbọ̀, ki o si dì i mọ ẹgbẹ rẹ, ki o má si fi i sinu omi.

2. Bẹ̃ li emi si rà àmure na, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, emi si dì i mọ ẹgbẹ mi.

3. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wa lẹ̃keji wipe:

4. Mu amure ti iwọ ti rà, ti o wà li ẹgbẹ rẹ, ki o si dide, lọ si odò Ferate, ki o si fi i pamọ nibẹ, ninu pàlapála okuta.

5. Bẹ̃ni mo lọ, emi si fi i pamọ leti odò Ferate, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun mi.

6. O si ṣe lẹhin ọjọ pupọ, Oluwa wi fun mi pe, Dide, lọ si odò Ferate, ki o si mu amure nì jade, ti mo paṣẹ fun ọ lati fi pamọ nibẹ.

7. Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun.

8. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

9. Bayi li Oluwa wi, Gẹgẹ bi eyi na ni emi o bà igberaga Juda jẹ, ati igberaga nla Jerusalemu.

Ka pipe ipin Jer 13