Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 13:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi fun mi pe: Lọ, ki o si rà àmure aṣọ ọgbọ̀, ki o si dì i mọ ẹgbẹ rẹ, ki o má si fi i sinu omi.

2. Bẹ̃ li emi si rà àmure na, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, emi si dì i mọ ẹgbẹ mi.

3. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wa lẹ̃keji wipe:

4. Mu amure ti iwọ ti rà, ti o wà li ẹgbẹ rẹ, ki o si dide, lọ si odò Ferate, ki o si fi i pamọ nibẹ, ninu pàlapála okuta.

5. Bẹ̃ni mo lọ, emi si fi i pamọ leti odò Ferate, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun mi.

6. O si ṣe lẹhin ọjọ pupọ, Oluwa wi fun mi pe, Dide, lọ si odò Ferate, ki o si mu amure nì jade, ti mo paṣẹ fun ọ lati fi pamọ nibẹ.

7. Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun.

Ka pipe ipin Jer 13