Bayi li Oluwa wi si gbogbo awọn aladugbo buburu mi ti nwọn fi ọwọ kan ogún mi ti mo ti mu enia mi, Israeli, jogun. Sa wò o, emi o fa wọn tu kuro ni ilẹ wọn, emi o si fà ile Juda tu kuro larin wọn.