Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 11:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Oluwa si wi fun mi pe, Kede gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi ki ẹ si ṣe wọn.

7. Nitori ni kikilọ mo kilọ fun awọn baba nyin lati ọjọ ti mo ti mu wọn wá lati ilẹ Egipti, titi di oni, emi si nyara kilọ fun wọn, mo si nsọ wipe, Ẹ gbà ohùn mi gbọ́.

8. Sibẹsibẹ nwọn kò gbọ́, nwọn kò tẹti silẹ, nwọn si rìn, olukuluku wọn ni agidi ọkàn buburu wọn: nitorina emi o mu gbogbo ọ̀rọ majẹmu yi wá sori wọn, ti mo paṣẹ fun wọn lati ṣe; nwọn kò si ṣe e.

9. Oluwa si wi fun mi pe, A ri ìditẹ lãrin awọn ọkunrin Juda ati lãrin awọn olugbe Jerusalemu.

10. Nwọn yipada si ẹ̀ṣẹ iṣaju awọn baba wọn ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi; awọn wọnyi si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn: ile Israeli ati ile Juda ti dà majẹmu mi ti mo ba awọn baba wọn dá.

11. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, Emi o mu ibi wá sori wọn, ti nwọn kì yio le yẹba fun: bi nwọn tilẹ ke pè mi, emi kì yio fetisi igbe wọn.

12. Jẹ ki ilu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu ki o lọ, ki nwọn ki o si ke pe awọn ọlọrun ti nwọn ńsun turari fun, ṣugbọn lõtọ nwọn kì yio le gba wọn ni igba ipọnju wọn.

13. Nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃ni iye ọlọrun rẹ, iwọ Juda, ati bi iye ita Jerusalemu, bẹ̃ni iye pẹpẹ ti ẹnyin ti tẹ́ fun ohun itìju nì, pẹpẹ lati sun turari fun Baali.

14. Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn.

Ka pipe ipin Jer 11