Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 11:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi, ki ẹ si sọ fun awọn enia Juda ati awọn olugbe Jerusalemu,

3. Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Ifibu ni oluwarẹ̀ ti kò ba gbà ọ̀rọ majẹmu yi gbọ́,

4. Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin:

5. Ki emi ki o le mu ileri mi ṣẹ, ti mo ti bura fun awọn baba nyin, lati fun wọn ni ilẹ ti nṣàn fun wara ati fun oyin, gẹgẹ bi o ti ri li oni: mo si dahùn mo si wipe, Amin, Oluwa!

6. Oluwa si wi fun mi pe, Kede gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi ki ẹ si ṣe wọn.

7. Nitori ni kikilọ mo kilọ fun awọn baba nyin lati ọjọ ti mo ti mu wọn wá lati ilẹ Egipti, titi di oni, emi si nyara kilọ fun wọn, mo si nsọ wipe, Ẹ gbà ohùn mi gbọ́.

8. Sibẹsibẹ nwọn kò gbọ́, nwọn kò tẹti silẹ, nwọn si rìn, olukuluku wọn ni agidi ọkàn buburu wọn: nitorina emi o mu gbogbo ọ̀rọ majẹmu yi wá sori wọn, ti mo paṣẹ fun wọn lati ṣe; nwọn kò si ṣe e.

9. Oluwa si wi fun mi pe, A ri ìditẹ lãrin awọn ọkunrin Juda ati lãrin awọn olugbe Jerusalemu.

10. Nwọn yipada si ẹ̀ṣẹ iṣaju awọn baba wọn ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi; awọn wọnyi si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn: ile Israeli ati ile Juda ti dà majẹmu mi ti mo ba awọn baba wọn dá.

11. Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, Emi o mu ibi wá sori wọn, ti nwọn kì yio le yẹba fun: bi nwọn tilẹ ke pè mi, emi kì yio fetisi igbe wọn.

Ka pipe ipin Jer 11