Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 1:17-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ṣugbọn iwọ di ẹ̀gbẹ́ rẹ li amure, ki o si dide, ki o si wi fun wọn gbogbo ohun ti emi o pa laṣẹ fun ọ, má fòya niwaju wọn, ki emi ki o má ba mu ọ dãmu niwaju wọn.

18. Sa wò o, loni ni mo fi ọ ṣe ilu-odi, ati ọwọ̀n irin, ati odi idẹ fun gbogbo ilẹ; fun awọn ọba Juda, awọn ijoye rẹ̀, awọn alufa, ati enia ilẹ na.

19. Ṣugbọn nwọn o ba ọ jà, nwọn kì o si le bori rẹ; nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ.

Ka pipe ipin Jer 1