Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 1:13-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá lẹ̃keji pe, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ìkoko ori iná, oju rẹ̀ si ni lati iha ariwa wá.

14. Nigbana ni Oluwa sọ fun mi pe, ibi yio tú jade lati ariwa wá, sori gbogbo awọn ti ngbe inu ilẹ.

15. Sa wò o, Emi o pè gbogbo idile awọn ijọba ariwa, li Oluwa wi, nwọn o si wá: olukuluku wọn o si tẹ́ itẹ rẹ̀ li ẹnu-bode Jerusalemu, ati lori gbogbo odi rẹ̀ yikakiri, ati lori gbogbo ilu Juda.

16. Emi o si sọ̀rọ idajọ mi si wọn nitori gbogbo buburu wọn; ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ti nwọn si tẹriba fun iṣẹ ọwọ wọn.

Ka pipe ipin Jer 1