Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 9:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.

7. Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.

8. Oluwa rán ọ̀rọ si Jakobu, o si ti bà lé Israeli.

9. Gbogbo enia yio si mọ̀ ọ, Efraimu ati awọn ti ngbe Samaria, ti nwi ninu igberaga, ati lile aiya pe,

10. Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.

11. Nitorina li Oluwa yio gbe awọn aninilara Resini dide si i, yio si dá awọn ọtá rẹ̀ pọ̀.

12. Awọn ara Siria niwaju, ati awọn Filistini lẹhin: nwọn o si fi gbogbo ẹnu jẹ Israeli run. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.

13. Awọn enia na kọ yipada si ẹniti o lù wọn, bẹ̃ni nwọn kò wá Oluwa awọn ọmọ-ogun.

14. Nitorina ni Oluwa yio ke ori ati irù, imọ̀-ọpẹ ati koriko-odo kuro ni Israeli, li ọjọ kan.

15. Agbà ati ọlọla, on li ori, ati wolĩ ti nkọni li eké, on ni irù.

Ka pipe ipin Isa 9