Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.