Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 8:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.

10. Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.

11. Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,

12. Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya.

13. Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.

14. On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.

15. Ọ̀pọlọpọ ninu wọn yio si kọsẹ, nwọn o si ṣubu, a o si fọ wọn, a o si mu wọn.

16. Di ẹri na, fi edídi di ofin na lãrin awọn ọmọ-ẹhin mi.

Ka pipe ipin Isa 8