Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 8:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi.

4. Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.

5. Oluwa si tun wi fun mi pe,

6. Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.

7. Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.

8. Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.

9. Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.

10. Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.

11. Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,

12. Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya.

13. Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.

14. On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.

Ka pipe ipin Isa 8