Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 8:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.

14. On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.

15. Ọ̀pọlọpọ ninu wọn yio si kọsẹ, nwọn o si ṣubu, a o si fọ wọn, a o si mu wọn.

16. Di ẹri na, fi edídi di ofin na lãrin awọn ọmọ-ẹhin mi.

17. Emi o si duro de Oluwa, ti o pa oju rẹ̀ mọ kuro lara ile Jakobu, emi o si ma wo ọ̀na rẹ̀.

18. Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wà fun àmi ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti ngbe òke Sioni.

19. Nigbati nwọn ba si wi fun nyin pe, Ẹ wá awọn ti mba okú lò, ati awọn oṣó ti nke, ti nsi nkùn, kò ha yẹ ki orilẹ-ède ki o wá Ọlọrun wọn jù ki awọn alãye ma wá awọn okú?

20. Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọ̀rọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni.

21. Nwọn o si kọja lọ lãrin rẹ̀, ninu inilara ati ebi: yio si ṣe pe nigbati ebi yio pa wọn, nwọn o ma kanra, nwọn o si fi ọba ati Ọlọrun wọn re, nwọn o si ma wò òke.

22. Nwọn o si wò ilẹ, si kiyesi i, iyọnu ati okùnkun, iṣuju irora: a o si le wọn lọ sinu okùnkun.

Ka pipe ipin Isa 8