Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 64:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ.

2. Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ!

3. Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ.

4. Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e.

5. Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là?

6. Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ.

7. Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa.

8. Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ.

9. Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.

Ka pipe ipin Isa 64