Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 61:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.

2. Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu.

3. Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo.

4. Nwọn o si mọ ibi ahoro atijọ wọnni, nwọn o gbe ahoro atijọ wọnni ro, nwọn o si tun ilu wọnni ti o ṣofo ṣe, ahoro iran ọ̀pọlọpọ.

Ka pipe ipin Isa 61