Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 60:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DIDE, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo Oluwa si yọ lara rẹ.

2. Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn Oluwa yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rẹ̀ lara rẹ.

3. Awọn keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ.

4. Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ.

5. Nigbana ni iwọ o ri, oju rẹ o si mọlẹ, ọkàn rẹ yio si yipada, yio si di nla: nitori a o yi ọrọ̀ okun pada si ọ, ipá awọn Keferi yio wá sọdọ rẹ.

6. Ọ̀pọlọpọ rakunmi yio bò ọ mọlẹ, awọn ọmọ rakunmi Midiani on Ẹfa; gbogbo wọn o wá lati Ṣeba: nwọn o mu wura ati turari wá; nwọn o fi iyìn Oluwa hàn sode.

7. A o ṣà gbogbo ọwọ́-ẹran Kedari jọ sọdọ rẹ, awọn àgbo Nebaioti yio ṣe iranṣẹ fun ọ; nwọn o goke wá si pẹpẹ mi pẹlu itẹwọgba, emi o si ṣe ile ogo mi li ogo.

8. Tani wọnyi ti nfò bi awọsanma, ati bi awọn ẹiyẹle si ojule wọn?

9. Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ọ̀na jìjin wá, fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ́ Israeli, nitoriti on ti ṣe ọ logo.

10. Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ.

11. Nitori na awọn ẹnu-bodè rẹ yio ṣi silẹ nigbagbogbo; a kì yio se wọn lọsan tabi loru, ki a le mu ọla awọn Keferi wá sọdọ rẹ, ki a ba si mu awọn ọba wọn wá.

Ka pipe ipin Isa 60