Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 6:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye.

10. Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ́, mú ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o má ba fi eti wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba mu wọn li ara dá.

11. Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata.

12. Titi Oluwa yio fi ṣi awọn enia na kuro lọ rére, ti ikọ̀silẹ nla yio si wà ni inu ilẹ na.

13. Ṣugbọn sibẹ, idamẹwa yio wà ninu rẹ̀, yio si padà, yio si di rirun, bi igi teili, ati bi igi oakù eyiti ọpá wà ninu wọn, nigbati ewe wọn ba rẹ̀: bẹ̃ni iru mimọ́ na yio jẹ ọpá ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 6