Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 59:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nwọn npa ẹyin pamọlẹ, nwọn nhun okùn alantakùn: ẹniti o jẹ ninu ẹyin wọn yio kú, ati eyi ti a tẹ̀ bẹ́ ọká jade.

6. Okùn wọn kì yio di ẹwù, bẹ̃ni nwọn kì yio fi iṣẹ wọn bò ara wọn: iṣẹ wọn ni iṣẹ ikà, iṣe ipá si mbẹ li ọwọ́ wọn.

7. Ẹsẹ wọn sare si ibi, nwọn si yara lati tajẹ̀ alaiṣẹ̀ silẹ: èro wọn èro ibi ni; ibajẹ ati iparun mbẹ ni ipa wọn.

8. Ọ̀na alafia ni nwọn kò mọ̀; kò si idajọ kan ninu ìrin wọn: nwọn ṣe ipa-ọ̀na wiwọ́ fun ara wọn: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ ọ kì yio mọ̀ alafia.

9. Nitori na ni idajọ jìna si wa, bẹ̃ni ododo kì yio le wa bá, awa duro dè imọlẹ, ṣugbọn kiyesi i, okunkun, a duro de imọlẹ, ṣugbọn a nrin ninu okunkun.

10. A nwá ogiri kiri bi afọju, awa si nwá ọ̀na bi ẹniti kò li oju: awa nkọsẹ lọsangangan bi ẹnipe loru, ni ibi ahoro, bi okú.

11. Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa.

Ka pipe ipin Isa 59