Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 59:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Gbogbo wa mbu bi beari, awa si npohunrere bi oriri: awa wò ọ̀na fun idajọ, ṣugbọn kò si, fun igbala, ṣugbọn o jìna si wa.

12. Nitori irekọja wa npọ̀ si i niwaju rẹ, ẹ̀ṣẹ wa njẹri gbè wa, nitori irekọja wa mbẹ lọdọ wa, niti aiṣedede wa, awa mọ̀ wọn.

13. Ni rirekọja ati ṣiṣeke si Oluwa, ifaṣẹhin kuro lọdọ Ọlọrun wa, isọrọ inilara ati ìṣọtẹ, liloyun ati sisọrọ eke lati inu jade wá.

14. A dá idajọ pada, ẹtọ́ si duro lokerè rére: otitọ ṣubu ni igboro, aiṣègbe kò le wọ ile.

15. Otitọ kò si, ẹniti o si kuro ninu ibi o sọ ara rẹ̀ di ijẹ: Oluwa si ri i, o si buru loju rẹ̀, ti idajọ kò si.

16. O si ri pe kò si ẹnikan, ẹnu si yà a pe onipẹ̀ kò si, nitorina apá rẹ̀ mu igbala fun u wá; ati ododo rẹ̀, on li o gbé e ró.

Ka pipe ipin Isa 59