Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 59:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, ọwọ́ Oluwa kò kuru lati gbàni, bẹ̃ni eti rẹ̀ kò wuwo ti kì yio fi gbọ́.

2. Ṣugbọn aiṣedede nyin li o yà nyin kuro lọdọ Ọlọrun nyin, ati ẹ̀ṣẹ nyin li o pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ nyin, ti on kì yio fi gbọ́.

3. Nitori ọwọ́ nyin di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ, ati ika nyin fun aiṣedede, ète nyin nsọ eke, ahọn nyin nsọ ibi jade.

4. Kò si ẹniti nwá ẹtọ́, bẹ̃ni kò si ẹniti ndajọ ni otitọ: nwọn gbẹkẹle ohun asan, nwọn nsọ eke; nwọn loyun ikà, nwọn mbí iparun.

Ka pipe ipin Isa 59