Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 56:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.

8. Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.

9. Gbogbo ẹnyin ẹranko igbẹ, ẹ wá lati pajẹ ani gbogbo ẹranko igbẹ.

10. Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé.

11. Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.

12. Ẹ wá, ni nwọn wi, emi o mu ọti-waini wá, a o si mu ọti-lile li amuyo; ọla yio si dabi ọjọ oni, yio si pọ̀ lọpọlọpọ.

Ka pipe ipin Isa 56