Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 56:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn.

2. Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi.

3. Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi.

4. Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu;

5. Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro.

6. Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu;

7. Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.

Ka pipe ipin Isa 56