Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 51:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.

12. Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.

13. Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà?

14. Ondè ti a ti ṣí nipo yara ki a ba le tú u silẹ, ati ki o má ba kú sinu ihò, tabi ki onjẹ rẹ̀ má ba tán.

15. Ṣugbọn emi Oluwa Ọlọrun rẹ ti o pin okun ni iyà, eyi ti ìgbi rẹ̀ nhó; Oluwa awọn ọmọ-ogun ni orukọ rẹ̀.

16. Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi.

17. Ji, ji, dide duro, iwọ Jerusalemu, ti o ti mu li ọwọ́ Oluwa ago irúnu rẹ̀; iwọ ti mu gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago ìwarìri, iwọ si fọ́n wọn jade.

18. Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba.

19. Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu?

20. Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ.

21. Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini:

22. Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ.

23. Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.

Ka pipe ipin Isa 51