Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 39:5-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbana ni Isaiah wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun:

6. Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi.

7. Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni.

8. Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere ni ọ̀rọ Oluwa ti iwọ ti sọ. O si wi pẹlu pe, Alafia ati otitọ́ yio sa wà li ọjọ mi.

Ka pipe ipin Isa 39