Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 38:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Kiyesi i, mo ti ni ikorò nla nipò alafia: ṣugbọn iwọ ti fẹ́ ọkàn mi lati ihò idibàjẹ wá: nitori iwọ ti gbe gbogbo ẹ̀ṣẹ mi si ẹ̀hin rẹ.

18. Nitori ibojì kò le yìn ọ, ikú kò le fiyìn fun ọ: awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò kò le ni irèti otitọ rẹ.

19. Alãyè, alãyè, on ni yio yìn ọ, bi mo ti nṣe loni yi: baba yio fi otitọ rẹ hàn fun awọn ọmọ.

20. Oluwa mura tan lati gbà mi: nitorina a o kọ orin mi lara dùrù olokùn, ni gbogbo ọjọ aiye wa ni ile Oluwa.

21. Nitori Isaiah ti wipe, Ki nwọn mu ìṣu ọ̀pọtọ́, ki a si fi ṣán õwo na, yio si sàn.

22. Hesekiah pẹlu ti wipe, Kili àmi na pe emi o goke lọ si ile Oluwa?

Ka pipe ipin Isa 38