Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 34:8-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni.

9. Odò rẹ̀ li a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi-õrun, ilẹ rẹ̀ yio si di ọ̀dà ti njona.

10. A kì o pa a li oru tabi li ọsan; ẹ̃fin rẹ̀ yio goke lailai: yio dahoro lati iran de iran; kò si ẹnikan ti yio là a kọja lai ati lailai.

11. Ṣugbọn ẹiyẹ ofú ati àkala ni yio ni i; ati owiwi ati iwò ni yio ma gbe inu rẹ̀: on o si nà okùn iparun sori rẹ̀, ati okuta ofo.

12. Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan kì yio si nibẹ ti nwọn o pè wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yio si di asan.

13. Ẹgún yio si hù jade ninu ãfin rẹ̀ wọnni, ẹgún ọ̀gan ninu ilú olodi rẹ̀: yio jẹ ibugbé awọn dragoni, ati agbalá fun awọn owiwi.

14. Awọn ẹran ijù ati awọn ọ̀wawa ni yio pade, ati satire kan yio ma kọ si ekeji rẹ̀; iwin yio ma gbe ibẹ̀ pẹlu, yio si ri ibí isimi fun ara rẹ̀.

15. Owiwi yio tẹ́ itẹ́ rẹ̀ sibẹ̀, yio yé, yio si pa, yio si kojọ labẹ ojiji rẹ̀: awọn gúnugú yio pejọ sibẹ pẹlu, olukuluku pẹlu ẹnikeji rẹ̀.

16. Ẹ wá a ninu iwe Oluwa, ẹ si kà a: ọkan ninu wọnyi kì yio yẹ̀, kò si ọkan ti yio fẹ́ ekeji rẹ̀ kù: nitori ẹnu mi on li o ti paṣẹ, ẹmi rẹ̀ li o ti ko wọn jọ.

17. On ti dì ìbo fun wọn, ọwọ́ rẹ̀ si fi tita okùn pin i fun wọn: nwọn o jogun rẹ̀ lailai, lati iran de iran ni nwọn o ma gbe inu rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 34