Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 31:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.

5. Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si.

6. Ẹ yipadà si ẹniti ẹ ti nṣọ̀tẹ si gidigidi, ẹnyin ọmọ Israeli.

7. Nitori li ọjọ na ni olukuluku enia yio jù ere fadaka rẹ̀, ati ere wura rẹ̀ nù, ti ọwọ́ ẹnyin tikara nyin ti ṣe fun ẹ̀ṣẹ fun nyin.

8. Nigbana ni ara Assiria na yio ṣubú nipa idà, ti kì iṣe nipa idà ọkunrin, ati idà, ti ki iṣe ti enia yio jẹ ẹ: ṣugbọn on o sá kuro niwaju idà, awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ma sìnrú.

9. Apata rẹ̀ yio kọja lọ fun ẹ̀ru, awọn olori rẹ̀ yiọ bẹ̀ru asia na, ni Oluwa wi, ẹniti iná rẹ̀ wà ni Sioni, ati ileru rẹ̀ ni Jerusalemu.

Ka pipe ipin Isa 31