Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 31:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa!

2. Ṣugbọn on gbọ́n pẹlu, o si mu ibi wá, kì yio si dá ọ̀rọ rẹ̀ padà: on si dide si ile awọn oluṣe buburu, ati si oluranlọwọ awọn ti nṣiṣẹ aiṣedede.

3. Nitori enia li awọn ara Egipti, nwọn kì iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn kì si iṣe ẹmi. Oluwa yio si nà ọwọ́ rẹ̀, ki ẹniti nràn ni lọwọ ba le ṣubu, ati ki ẹniti a nràn lọwọ ba lè ṣubu, gbogbo wọn o jùmọ ṣegbe.

4. Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.

5. Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si.

6. Ẹ yipadà si ẹniti ẹ ti nṣọ̀tẹ si gidigidi, ẹnyin ọmọ Israeli.

Ka pipe ipin Isa 31