Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 3:16-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro:

17. Nitorina Oluwa yio fi ẽpá lu atàri awọn ọmọbinrin Sioni, Oluwa yio si fi ihoho wọn hàn.

18. Li ọjọ na Oluwa yio mu ogo ṣaworo wọn kuro, ati awọn ọṣọ́ wọn, ati iweri wọn bi oṣupa.

19. Ati ẹ̀wọn, ati jufù, ati ìboju,

20. Ati akẹtẹ̀, ati ohun ọṣọ́-ẹsẹ, ati ọjá-ori, ati ago olõrùn didùn, ati oruka eti,

21. Oruka, ati ọṣọ́-imu,

22. Ipãrọ̀ aṣọ wiwọ, ati aṣọ ilekè, ati ibọ̀run, ati àpo,

23. Awòjiji, ati aṣọ ọ̀gbọ daradara, ati ibòri ati ibòju,

24. Yio si ṣe pe, õrun buburu yio wà dipò õrun didùn; akisà ni yio si dipò amùre; ori pipá ni yio si dipò irun didì daradara; sisan aṣọ ọ̀fọ dipò igbaiya, ijoná yio si dipò ẹwà.

25. Awọn ọkunrin rẹ yio ti ipa idà ṣubu, ati awọn alagbara rẹ loju ogun.

26. Awọn bodè rẹ̀ yio pohùnrere ẹkun, nwọn o si ṣọ̀fọ; ati on, nitori o di ahoro, yio joko ni ilẹ.

Ka pipe ipin Isa 3