Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 28:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nitori Oluwa yio dide bi ti oke Perasimu, yio si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibeoni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ̀, iṣẹ àrà rẹ̀; yio si mu iṣe rẹ̀ ṣẹ, ajeji iṣe rẹ̀.

22. Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ.

23. Ẹ fetisilẹ, ẹ si gbọ́ ohùn mi: ẹ tẹtilelẹ, ẹ si gbọ́ ọ̀rọ mi.

24. Gbogbo ọjọ ni agbẹ̀ ha nroko lati gbìn? on o ha ma tú, a si ma fọ́ ilẹ rẹ̀ bi?

25. Nigbati on ti tẹ́ ojú rẹ̀ tan, on kò ha nfunrugbìn dili, ki o si fọn irugbìn kummini ka, ki o si gbìn alikama lẹsẹ-ẹsẹ, ati barle ti a yàn, ati spelti nipò rẹ̀?

26. Nitori Ọlọrun rẹ̀ kọ́ ọ lati ni oye, o tilẹ kọ́ ọ.

27. Nitori a kò fi ohun-elò pakà dili, bẹ̃ni a kì iyí kẹkẹ́ kiri lori kummini; ṣugbọn ọpá li a ifi pa dili jade, ọgọ li a si fi lù kummini.

28. Akara agbado li a lọ̀; on kò le ma pa a titi, bẹ̃ni kò fi kẹkẹ́-ẹrù fọ́ ọ, bẹ̃ni kì ifi awọn ẹlẹṣin rẹ̀ tẹ̀ ẹ.

29. Eyi pẹlu ti ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ẹniti o kún fun iyanu ni ìmọ, ti o tayọ ni iṣe.

Ka pipe ipin Isa 28