Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 28:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun ade igberaga, fun awọn ọmuti Efraimu, ati fun itàna rirọ ti ogo ẹwà rẹ̀, ti o wà lori afonifoji ọlọra ti awọn ti ọti-waini pa.

2. Kiye si i, Oluwa ni ẹnikan alagbara ati onipá, bi ẹfũfu lile, yiyin, ati ìji iparun, bi iṣàn-omi nla àkúnya, yio fi ọwọ́ bì ṣubu sori ilẹ.

3. Ade igberaga, awọn ọmuti Efraimu, li a o fi ẹsẹ tẹ̀ mọlẹ:

4. Ati ogo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọra, yio jẹ itanna rirọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaju igba ìkore; eyiti nigbati ẹniti o ba nwò o ba ri, nigbati o wà li ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbe e mì.

5. Li ọjọ na li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jẹ ade ogo, ati ade ẹwà fun iyokù awọn enia rẹ̀,

6. Ati ẹmi idajọ fun awọn ẹniti o joko ni idajọ, ati agbara fun awọn ti o le ogun padà si ibode.

7. Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ.

8. Nitori gbogbo tabili li o kún fun ẽbi ati ẹgbin, kò si ibi ti o mọ́.

9. Tani on o kọ́ ni ìmọ? ati tani on o fi oye ẹkọ́ yé? awọn ẹniti a wọ́n li ẹnu-ọmú, ti a si já li ẹnu ọyàn.

10. Nitori aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ; ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun:

11. Nitori nipa ète ẹlẹyà ati ni ède miran li on o fi bá enia wọnyi sọ̀rọ.

12. Si ẹniti on wipe, Eyi ni isimi, ẹnyin ìba mu awọn alãrẹ̀ simi; eyi si ni itura: sibẹ nwọn kì yio gbọ́.

13. Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.

14. Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu.

15. Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ:

Ka pipe ipin Isa 28