Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 27:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọjọ na li Oluwa yio fi idà rẹ̀ mimú ti o tobi, ti o si wuwo bá lefiatani ejò ti nfò wi, ati lefiatani ejò wiwọ́ nì; on o si pa dragoni ti mbẹ li okun.

2. Li ọjọ na ẹ kọrin si i, Ajàra ọti-waini pipọ́n.

3. Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan.

4. Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan.

5. Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà.

6. Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye.

7. On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa?

8. Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun.

Ka pipe ipin Isa 27