Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 24:3-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ilẹ yio di ofo patapata, yio si bajẹ patapata: nitori Oluwa ti sọ ọ̀rọ yi.

4. Ilẹ̀ nṣọ̀fọ o si nṣá, aiye nrù o si nṣá, awọn ẹni giga ilẹ njoro.

5. Ilẹ pẹlu si di aimọ́ li abẹ awọn ti ngbe inu rẹ̀; nitori nwọn ti rú ofin, nwọn pa ilàna dà, nwọn dà majẹmu aiyeraiye.

6. Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù.

7. Ọti-waini titun nṣọ̀fọ, àjara njoro, gbogbo awọn ti nṣe aríya nkẹdùn.

8. Ayọ̀ tabreti dá, ariwo awọn ti nyọ̀ pin, ayọ̀ harpu dá.

9. Nwọn kì yio fi orin mu ọti-waini mọ́; ọti-lile yio koro fun awọn ti nmu u.

10. A wó ilu rúdurudu palẹ: olukuluku ile li a se, ki ẹnikan má bà wọle.

11. Igbe fun ọti-waini mbẹ ni igboro; gbogbo ayọ̀ ṣú òkunkun, aríya ilẹ na lọ.

12. Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.

Ka pipe ipin Isa 24