Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 24:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, Oluwa sọ aiye di ofo, o si sọ ọ di ahoro, o si yi i po, o si tú awọn olugbé inu rẹ̀ ka.

2. Yio si ṣe, bi o ti ri fun awọn enia, bẹ̃li o ri fun alufa; bi o ti ri fun iranṣẹ-kunrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun iranṣẹbinrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun olùra, bẹ̃ni fun olùta; bi o ti ri fun awinni, bẹ̃ni fun atọrọ; bi o ti ri fun agbà elé, bẹ̃ni fun ẹniti o san ele fun u.

3. Ilẹ yio di ofo patapata, yio si bajẹ patapata: nitori Oluwa ti sọ ọ̀rọ yi.

4. Ilẹ̀ nṣọ̀fọ o si nṣá, aiye nrù o si nṣá, awọn ẹni giga ilẹ njoro.

5. Ilẹ pẹlu si di aimọ́ li abẹ awọn ti ngbe inu rẹ̀; nitori nwọn ti rú ofin, nwọn pa ilàna dà, nwọn dà majẹmu aiyeraiye.

Ka pipe ipin Isa 24