Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 23:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye?

9. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan.

10. La ilẹ rẹ ja bi odò, iwọ ọmọbinrin Tarṣiṣi: àmure kò si mọ́.

11. O nà ọwọ́ rẹ̀ jade si oju okun, o mì awọn ijọba: Oluwa ti pa aṣẹ niti Kenaani, lati run agbàra inu rẹ̀.

12. On si wipe, Iwọ kò gbọdọ yọ̀ mọ, iwọ wundia ti a ni lara, ọmọbinrin Sidoni; dide rekọja lọ si Kittimu, nibẹ pẹlu iwọ kì yio ri isimi.

13. Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run.

14. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro.

15. Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin.

16. Mu harpu kan, kiri ilu lọ, iwọ panṣaga obinrin ti a ti gbagbe; dá orin didùn: kọ orin pupọ̀ ki a le ranti rẹ.

17. Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere.

18. Ọjà rẹ̀ ati ọ̀ya rẹ̀ yio jẹ mimọ́ si Oluwa: a kì yio fi ṣura, bẹ̃li a ki yio tò o jọ; nitori ọjà rẹ̀ yio jẹ ti awọn ti ngbe iwaju Oluwa, lati jẹ ajẹtẹrùn, ati fun aṣọ daradara.

Ka pipe ipin Isa 23