Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 23:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti Tire. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi; nitoriti a o sọ ọ di ahoro, tobẹ̃ ti kò si ile, kò si ibi wiwọ̀: a fi hàn fun wọn lati ilẹ Kittimu.

2. Ẹ duro jẹ, ẹnyin olugbé erekùṣu; iwọ ẹniti awọn oniṣowo Sidoni, ti nre okun kọja ti kún.

3. Ati nipa omi nla iru Sihori, ikorè odò, ni owo ọdun rẹ̀; on ni ọjà awọn orilẹ-ède.

4. Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.

5. Gẹgẹ bi ihìn niti Egipti, bẹ̃ni ara yio ro wọn goro ni ihìn Tire.

6. Ẹ kọja si Tarṣiṣi; hu, ẹnyin olugbé erekùṣu.

7. Eyi ha ni ilu ayọ̀ fun nyin, ti o ti wà lati ọjọ jọjọ? ẹsẹ on tikara rẹ̀ yio rù u lọ si ọna jijìn rére lati ṣe atipó.

8. Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye?

9. Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan.

Ka pipe ipin Isa 23