Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 22:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Lọ, tọ olutọju yi lọ, ani tọ Ṣebna lọ, ti iṣe olori ile,

16. Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta?

17. Kiyesi i, Oluwa yio fi sisọ agbara sọ ọ nù, yio si bò ọ mọlẹ.

18. Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.

19. Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ.

20. Yio si ṣe li ọjọ na, ni emi o pè Eliakimu iranṣẹ mi ọmọ Hilkiah.

21. Emi o si fi aṣọ-igunwà rẹ wọ̀ ọ, emi o si fi àmure rẹ dì i, emi o si fi ijọba rẹ le e li ọwọ́: on o si jẹ baba fun awọn olugbé Jerusalemu, ati fun ile Juda.

22. Iṣikà ile Dafidi li emi o fi le èjiká rẹ̀: yio si ṣí, kò si ẹniti yio tì; on o si tì, kò si si ẹniti yio ṣí.

23. Emi o si kàn a bi iṣó ni ibi ti o le, on o jẹ fun itẹ ogo fun ile baba rẹ̀.

24. Gbogbo ogo ile baba rẹ̀ ni nwọn o si fi kọ́ ọ li ọrùn, ati ọmọ ati eso, gbogbo ohun-elò ife titi de ago ọti.

25. Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Li ọjọ na, ni a o ṣi iṣó ti a kàn mọ ibi ti o le ni ipò, a o si ke e lu ilẹ, yio si ṣubu; ẹrù ara rẹ̀ li a o ké kuro: nitori Oluwa ti sọ ọ.

Ka pipe ipin Isa 22