12. Ati li ọjọ na ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio pè lati sọkun, ati lati ṣọ̀fọ, ati lati fá ori, ati lati sán aṣọ ọ̀fọ.
13. Si kiyesi i, ayọ̀ ati inu-didùn, pipa malũ, ati pipa agutan, jijẹ ẹran, ati mimu ọti-waini: ẹ jẹ ki a ma jẹ, ki a si ma mu; nitori ọla li awa o kú.
14. Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
15. Bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Lọ, tọ olutọju yi lọ, ani tọ Ṣebna lọ, ti iṣe olori ile,
16. Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta?
17. Kiyesi i, Oluwa yio fi sisọ agbara sọ ọ nù, yio si bò ọ mọlẹ.
18. Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.
19. Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ.