Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 22:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata?

2. Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun.

3. Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá.

4. Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi.

5. Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla.

6. Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ.

7. Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi.

8. On si ri iboju Juda, iwọ si wò li ọjọ na ihamọra ile igbó.

9. Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ.

10. Ẹnyin ti kà iye ile Jerusalemu, awọn ile na li ẹnyin biwó lati mu odi le.

11. Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni,

Ka pipe ipin Isa 22