Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 21:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.

11. Ọ̀rọ-ìmọ niti Duma. O ké si mi lati Seiri wá, Oluṣọ́, oru ti ri? Oluṣọ́ oru ti ri?

12. Oluṣọ́ wipe, ilẹ nmọ́ bọ̀, alẹ si nlẹ pẹlu: bi ẹnyin o ba bere, ẹ bere: ẹ pada, ẹ wá.

13. Ọ̀rọ-ìmọ niti Arabia. Ninu igbó Arabia li ẹnyin o wọ̀, ẹnyin ẹgbẹ́-erò Dedanimu.

14. Awọn olugbé ilẹ Tema bù omi wá fun ẹniti ongbẹ ngbẹ, onjẹ wọn ni nwọn fi ṣaju ẹniti nsalọ.

15. Nitori nwọn nsá fun idà, fun idà fifayọ, ati fun ọrun kikàn, ati fun ibinujẹ ogun.

16. Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, ki ọdun kan to pe, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, gbogbo ogo Kedari yio wọ̀.

17. Iyokù ninu iye awọn tafàtafà, awọn alagbara ninu awọn ọmọ Kedari yio dinkù: nitori Oluwa Ọlọrun Israeli ti wi i.

Ka pipe ipin Isa 21