Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 21:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru.

2. Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.

3. Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.

4. Ọkàn mi nrò, ẹ̀ru dẹrùba mi: oru ayọ̀ mi li o ti sọ di ìbẹru fun mi.

5. Pèse tabili silẹ, yàn alore, jẹ, mu: dide, ẹnyin ọmọ-alade, ẹ kùn asà nyin.

6. Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, Lọ, fi ẹnikan ṣọ ọ̀na, jẹ ki o sọ ohun ti o ri.

7. O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi:

8. On si kigbe pe, kiniun kan: Oluwa mi, nigbagbogbo li emi nduro lori ile-iṣọ li ọsan, a si fi mi si iṣọ mi ni gbogbo oru:

9. Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ.

10. Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.

11. Ọ̀rọ-ìmọ niti Duma. O ké si mi lati Seiri wá, Oluṣọ́, oru ti ri? Oluṣọ́ oru ti ri?

12. Oluṣọ́ wipe, ilẹ nmọ́ bọ̀, alẹ si nlẹ pẹlu: bi ẹnyin o ba bere, ẹ bere: ẹ pada, ẹ wá.

Ka pipe ipin Isa 21