Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 19:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bẹ̃ni kì yio si iṣẹkiṣẹ́ fun Egipti, ti ori tabi ìru, ẹka tabi oko-odò, le ṣe.

16. Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori.

17. Ilẹ Juda yio si di ẹ̀ru fun Egipti, olukuluku ẹniti o dá a sọ ninu rẹ̀ yio tikararẹ̀ bẹ̀ru, nitori ìmọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o ti gbà si i.

18. Li ọjọ na ni ilu marun ni ilẹ Egipti yio fọ̀ ède Kenaani, ti nwọn o sì bura si Oluwa awọn ọmọ-ogun; a o ma pè ọkan ni Ilu ìparun.

19. Li ọjọ na ni pẹpẹ kan yio wà fun Oluwa li ãrin ilẹ Egipti, ati ọwọ̀n ni àgbegbe inu rẹ̀ fun Oluwa.

20. Yio si jẹ fun ami, ati fun ẹ̀ri si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ Egipti: nitori nwọn o kigbe pè Oluwa nitori awọn aninilara, yio si rán olugbala kan si i, ati ẹni-nla, on o si gbà wọn.

21. Oluwa yio si di mimọ̀ fun Egipti, awọn ara Egipti yio so mọ́ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si rú ẹbọ, nwọn o si ta ọrẹ; nitõtọ nwọn o jẹ'jẹ fun Oluwa, nwọn o si mu u ṣẹ.

22. Oluwa o si lù Egipti bolẹ, yio si mu u li ara da: nwọn o si yipada si Oluwa, on o si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn, yio si mu wọn li ara da.

23. Li ọjọ na ni opopo kan yio wà lati Egipti de Assiria, awọn ara Assiria yio si wá si Egipti, awọn ara Egipti si Assiria, awọn ara Egipti yio si sìn pẹlu awọn ara Assiria.

24. Li ọjọ na ni Israeli yio jẹ ẹkẹta pẹlu Egipti ati pẹlu Assiria, ani ibukún li ãrin ilẹ na:

25. Ti Oluwa awọn ọmọ-ogun yio bukún fun, wipe, Ibukun ni fun Egipti enia mi, ati fun Assiria iṣẹ ọwọ́ mi, ati fun Israeli ini mi.

Ka pipe ipin Isa 19