Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 17:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti Damasku. Kiye si i, a mu Damasku kuro lati ma jẹ ilu, yi o si di òkiti àlapa.

2. A kọ̀ gbogbo ilu Aroeri silẹ: nwọn o jẹ ti ọ̀wọ-ẹran, ti yio dubulẹ, ẹnikẹni kì yio dẹrubà wọn.

3. Odi kì yio si si mọ ni Efraimu, ati ijọba ni Damasku, ati iyokù ti Siria: nwọn o dabi ogo awọn ọmọ Israeli, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

4. Li ọjọ na yio si ṣe, a o mu ogo Jakobu dinkù, ati sisanra ara rẹ̀ li a o sọ di rirù.

5. Yio si dabi igbati olukorè nkó agbado jọ, ti o si nfi apá rẹ̀ rẹ́ ipẹ́-ọkà yio si dabi ẹniti nkó ipẹ́-ọkà jọ ni afonifoji Refaimu.

6. Ṣugbọn ẽṣẹ́ eso-àjara yio hù ninu rẹ̀, gẹgẹ bi mimì igi olifi, eso kekere meji bi mẹta ni ṣonṣo oke ẹka mẹrin bi marun ni ẹka ode ti o ni eso pupọ, li Oluwa Ọlọrun Israeli wi.

7. Li ọjọ na li ẹnikan yio wò Ẹlẹda rẹ̀, ati oju rẹ̀ yio si bọ̀wọ fun Ẹni-Mimọ Israeli.

8. On kì yio si wò pẹpẹ, iṣẹ ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si bọ̀wọ fun eyi ti ika rẹ̀ ti ṣe, yala igbo-òriṣa tabi ere-õrun.

9. Li ọjọ na ni ilu alagbara rẹ̀ yio dabi ẹka ìkọsilẹ, ati ẹka tente oke ti nwọn fi silẹ nitori awọn ọmọ Israeli: iparun yio si wà.

Ka pipe ipin Isa 17