1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti Damasku. Kiye si i, a mu Damasku kuro lati ma jẹ ilu, yi o si di òkiti àlapa.
2. A kọ̀ gbogbo ilu Aroeri silẹ: nwọn o jẹ ti ọ̀wọ-ẹran, ti yio dubulẹ, ẹnikẹni kì yio dẹrubà wọn.
3. Odi kì yio si si mọ ni Efraimu, ati ijọba ni Damasku, ati iyokù ti Siria: nwọn o dabi ogo awọn ọmọ Israeli, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4. Li ọjọ na yio si ṣe, a o mu ogo Jakobu dinkù, ati sisanra ara rẹ̀ li a o sọ di rirù.